ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 7:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+

  • 2 Sámúẹ́lì 7:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Ilé rẹ àti ìjọba rẹ máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí láé níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ á sì fìdí múlẹ̀ títí láé.”’”+

  • 1 Àwọn Ọba 8:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn níwájú mi bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+

  • 1 Kíróníkà 17:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 “‘“Nígbà tí o bá kú, tí o sì lọ síbi tí àwọn baba ńlá rẹ wà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ,+ màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+

  • Sáàmù 132:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,

      Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé:

      “Ọ̀kan lára ọmọ* rẹ

      Ni màá gbé gorí ìtẹ́ rẹ.+

      12 Tí àwọn ọmọ rẹ bá pa májẹ̀mú mi mọ́

      Àti àwọn ìránnilétí mi tí mo kọ́ wọn,+

      Àwọn ọmọ tiwọn náà

      Yóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ títí láé.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́