-
2 Àwọn Ọba 17:21-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Ó fa Ísírẹ́lì ya kúrò ní ilé Dáfídì, wọ́n sì fi Jèróbóámù ọmọ Nébátì jọba.+ Àmọ́ Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì yà kúrò lẹ́yìn Jèhófà, ó sì mú kí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. 22 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń dá gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá.+ Wọn kò jáwọ́ nínú wọn 23 títí Jèhófà fi mú Ísírẹ́lì kúrò níwájú rẹ̀, bó ṣe sọ látẹnu gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.+ Bí wọ́n ṣe kó Ísírẹ́lì nígbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ lọ sí Ásíríà+ nìyẹn, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.
-