ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 16:30, 31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Ìwà Áhábù ọmọ Ómírì tún wá burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+ 31 Àfi bíi pé nǹkan kékeré ni lójú rẹ̀ bó ṣe ń rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ó tún fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Báálì,+ ó sì ń forí balẹ̀ fún un.

  • 2 Àwọn Ọba 3:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Jèhórámù+ ọmọ Áhábù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún kejìdínlógún Jèhóṣáfátì ọba Júdà, ọdún méjìlá (12) ló sì fi ṣàkóso.

  • 2 Àwọn Ọba 3:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Síbẹ̀, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá ni òun náà ń dá.+ Kò jáwọ́ nínú wọn.

  • 2 Àwọn Ọba 10:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Àmọ́ Jéhù ò kíyè sára láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa Òfin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́.+ Kò kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì dá.+

  • 2 Àwọn Ọba 13:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ní ọdún kẹtàlélógún Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà+ ọba Júdà, Jèhóáhásì ọmọ Jéhù+ di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ló sì fi ṣàkóso. 2 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, kò sì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Kò ṣíwọ́ nínú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́