ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 8:7-9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn,* tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde* ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè, 8 ilẹ̀ tí àlìkámà* àti ọkà bálì kún inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ tí òróró ólífì àti oyin kún inú rẹ̀,+ 9 ilẹ̀ tí oúnjẹ ò ti ní wọ́n ọ, tó ò sì ní ṣaláìní ohunkóhun, ilẹ̀ tí irin wà nínú àwọn òkúta rẹ̀, tí wàá sì máa wa bàbà látinú àwọn òkè rẹ̀.

  • Diutarónómì 29:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Torí náà, Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú àti ìkannú ńlá fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn,+ ó sì kó wọn lọ sí ilẹ̀ míì níbi tí wọ́n wà lónìí.’+

  • Jóṣúà 23:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àmọ́ bí gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín ṣe ṣẹ sí yín lára,+ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa mú gbogbo àjálù tó ṣèlérí* wá sórí yín, ó sì máa pa yín run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.+

  • 2 Àwọn Ọba 17:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà, ọba Ásíríà gba Samáríà.+ Ó wá kó àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ní ìgbèkùn+ lọ sí Ásíríà, ó sì mú kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì+ àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́