-
Léfítíkù 26:3-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “‘Tí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin mi, tí ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì ń ṣe wọ́n,+ 4 èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ,+ ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ àwọn igi oko yóò sì so èso. 5 Ẹ ó máa pakà títí di ìgbà tí ẹ máa kórè èso àjàrà, ẹ ó sì máa kórè èso àjàrà títí di ìgbà tí ẹ máa fúnrúgbìn; ẹ ó jẹun ní àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìséwu ní ilẹ̀ yín.+ 6 Màá mú kí àlàáfíà wà ní ilẹ̀ náà,+ ẹ ó sì dùbúlẹ̀ láìsí ẹni tó máa dẹ́rù bà yín;+ màá mú àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, idà ogun ò sì ní kọjá ní ilẹ̀ yín. 7 Ó dájú pé ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín, ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun wọn. 8 Ẹ̀yin márùn-ún yóò lé ọgọ́rùn-ún (100), ẹ̀yin ọgọ́rùn-ún (100) yóò lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín.+
9 “‘Màá ṣojúure* sí yín, màá mú kí ẹ bímọ lémọ, kí ẹ sì di púpọ̀,+ màá sì mú májẹ̀mú tí mo bá yín dá ṣẹ.+ 10 Bí ẹ ṣe ń jẹ irè oko tó ṣẹ́ kù láti ọdún tó kọjá, ẹ máa ní láti palẹ̀ èyí tó ṣẹ́ kù mọ́ kí tuntun lè wọlé. 11 Màá gbé àgọ́ ìjọsìn mi sáàárín yín,+ mi* ò sì ní kọ̀ yín. 12 Èmi yóò máa rìn láàárín yín, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì jẹ́ èèyàn mi.+
-