ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 3:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+

  • Léfítíkù 26:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ,+ ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ àwọn igi oko yóò sì so èso.

  • Diutarónómì 11:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ilẹ̀ tó ní àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ sọdá lọ gbà.+ Òjò tó ń rọ̀ láti ọ̀run ló ń bomi rin ín;+ 12 Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń bójú tó ilẹ̀ náà. Ojú Jèhófà Ọlọ́run yín kì í sì í kúrò ní ilẹ̀ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí di ìparí ọdún.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́