ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 7:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+

  • 2 Sámúẹ́lì 7:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+

  • Sáàmù 89:33-37
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 Àmọ́ mi ò ní mú ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ láé,+

      Mi ò sì ní ṣàì mú ìlérí mi ṣẹ.*

      34 Mi ò ní da májẹ̀mú mi,+

      Mi ò sì ní yí ohun tí ẹnu mi ti sọ pa dà.+

      35 Mo ti búra nínú ìjẹ́mímọ́ mi, lẹ́ẹ̀kan láìtún ṣe é mọ́;

      Mi ò ní parọ́ fún Dáfídì.+

      36 Àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò wà títí láé;+

      Ìtẹ́ rẹ̀ yóò wà títí lọ bí oòrùn níwájú mi.+

      37 Yóò fìdí múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá

      Bí ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé ní ojú ọ̀run.” (Sélà)

  • Àìsáyà 37:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 ‘Màá gbèjà ìlú yìí,+ màá sì gbà á sílẹ̀ nítorí orúkọ mi+

      Àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’”+

  • Jeremáyà 33:20, 21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí ẹ bá lè ba májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti májẹ̀mú mi nípa òru jẹ́, pé kí ọ̀sán àti òru má ṣe wà ní àkókò wọn+ 21 nìkan ni májẹ̀mú tí mo bá Dáfídì ìránṣẹ́ mi dá tó lè bà jẹ́,+ tí kò fi ní máa ní ọmọ tó ń jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni májẹ̀mú tí mo bá àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì dá, àwọn òjíṣẹ́ mi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́