-
2 Sámúẹ́lì 15:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń sunkún kíkankíkan nígbà tí àwọn èèyàn náà ń sọdá, ọba sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Kídírónì;+ gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sọdá sójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù.
-
-
2 Kíróníkà 15:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ọba Ásà tiẹ̀ tún yọ Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba,* torí pé ó ṣe òrìṣà ẹ̀gbin tí wọ́n fi ń jọ́sìn òpó òrìṣà.*+ Ásà gé òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀ lulẹ̀, ó rún un wómúwómú, ó sì sun ún ní Àfonífojì Kídírónì.+ 17 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò+ ní Ísírẹ́lì. + Síbẹ̀, Ásà fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọlọ́run* ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀.+ 18 Ó kó àwọn ohun tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò míì.+
-