-
1 Àwọn Ọba 9:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
-
-
1 Àwọn Ọba 16:30-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ìwà Áhábù ọmọ Ómírì tún wá burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+ 31 Àfi bíi pé nǹkan kékeré ni lójú rẹ̀ bó ṣe ń rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ó tún fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Báálì,+ ó sì ń forí balẹ̀ fún un. 32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ pẹpẹ kan fún Báálì ní ilé* Báálì+ tí ó kọ́ sí Samáríà. 33 Áhábù tún ṣe òpó òrìṣà.*+ Áhábù sì ṣe ohun tó bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì nínú ju gbogbo àwọn ọba Ísírẹ́lì tó jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ.
-