Jẹ́nẹ́sísì 32:28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 Ó wá sọ fún un pé: “O ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì*+ ni wàá máa jẹ́, torí o ti bá Ọlọ́run + àti èèyàn wọ̀jà, o sì ti wá borí.” Jẹ́nẹ́sísì 32:30 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 30 Torí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ ó dá ẹ̀mí* mi sí.”+ Jẹ́nẹ́sísì 35:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Ọlọ́run sọ fún un pé: “Jékọ́bù+ ni orúkọ rẹ. Àmọ́, o ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì ni wàá máa jẹ́.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ísírẹ́lì.+ Àìsáyà 48:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 48 Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+
28 Ó wá sọ fún un pé: “O ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì*+ ni wàá máa jẹ́, torí o ti bá Ọlọ́run + àti èèyàn wọ̀jà, o sì ti wá borí.”
30 Torí náà, Jékọ́bù pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ ó dá ẹ̀mí* mi sí.”+
10 Ọlọ́run sọ fún un pé: “Jékọ́bù+ ni orúkọ rẹ. Àmọ́, o ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì ni wàá máa jẹ́.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ísírẹ́lì.+
48 Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+