-
1 Àwọn Ọba 18:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fún wa ní akọ ọmọ màlúù méjì, kí wọ́n mú akọ ọmọ màlúù kan, kí wọ́n gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọ́n sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà á ṣètò akọ ọmọ màlúù kejì, màá sì kó o sórí igi, ṣùgbọ́n mi ò ní fi iná sí i. 24 Lẹ́yìn náà, kí ẹ pe orúkọ ọlọ́run yín,+ èmi náà á pe orúkọ Jèhófà. Ọlọ́run tí ó bá fi iná dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.”+ Gbogbo àwọn èèyàn náà bá dáhùn pé: “Ohun tí o sọ dáa.”
-