-
Léfítíkù 9:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Níkẹyìn, Mósè àti Áárónì lọ sínú àgọ́ ìpàdé, wọ́n jáde wá, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn náà.+
Jèhófà wá fi ògo rẹ̀ han gbogbo àwọn èèyàn náà,+ 24 iná sì bọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó ẹbọ sísun àti àwọn ọ̀rá tó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 6:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Áńgẹ́lì Jèhófà wá na orí ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kan ẹran àti búrẹ́dì aláìwú náà, iná sọ níbi àpáta náà, ó sì jó ẹran àti búrẹ́dì aláìwú+ náà run. Ni áńgẹ́lì Jèhófà bá pòórá mọ́ ọn lójú.
-