26 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ahasáyà nígbà tó jọba, ọdún kan ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ataláyà+ ọmọ ọmọ Ómírì+ ọba Ísírẹ́lì. 27 Ó ń ṣe ohun tí àwọn ará ilé Áhábù+ ṣe, ó sì ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ìyàwó ní ilé Áhábù.+