-
Àìsáyà 37:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ṣé o ò tíì gbọ́ ni? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti pinnu rẹ̀.*
Láti ọ̀pọ̀ ọjọ́ sẹ́yìn ni mo ti ṣètò rẹ̀.*+
Ní báyìí, màá ṣe é.+
Wàá sọ àwọn ìlú olódi di àwókù.+
27 Àwọn tó ń gbé inú wọn á di aláìlágbára;
Jìnnìjìnnì á bá wọn, ojú á sì tì wọ́n.
Wọ́n á rọ bí ewéko pápá àti bí koríko tútù ṣe máa ń rọ,
Bíi koríko orí òrùlé tí atẹ́gùn ìlà oòrùn ti jó gbẹ.
-