ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 23:36, 37
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 36 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jèhóákímù+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sébídà ọmọ Pedáyà láti Rúmà. 37 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà,+ gbogbo ohun tí àwọn bàbá ńlá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.+

  • Jeremáyà 24:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 “‘Àmọ́ ní ti ọ̀pọ̀tọ́ tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ,+ ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Bákan náà ni màá ṣe sí Sedekáyà+ ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù tó wà ní ilẹ̀ yìí àti àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì.+

  • Jeremáyà 37:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 37 Ọba Sedekáyà+ ọmọ Jòsáyà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù, nítorí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Júdà.+ 2 Àmọ́ òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí wòlíì Jeremáyà sọ.

  • Jeremáyà 38:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”

      6 Torí náà, wọ́n mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi Málíkíjà ọmọ ọba, èyí tó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Wọ́n fi okùn sọ Jeremáyà kalẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí omi nínú kòtò omi náà, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ náà.

  • Ìsíkíẹ́lì 21:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 “Àmọ́ ọjọ́ rẹ ti dé, ìgbà tí o máa jìyà ìkẹyìn ti dé, ìwọ ìjòyè tí wọ́n ti ṣe léṣe, ìjòyè burúkú ti Ísírẹ́lì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́