-
1 Àwọn Ọba 2:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì.+ 11 Gbogbo ọdún* tí Dáfídì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì (40) ọdún. Ọdún méje ló fi jọba ní Hébúrónì,+ ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33)+ jọba ní Jerúsálẹ́mù.
12 Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in.+
-