15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ Lọ́jọ́ kìíní, kí ẹ mú àpòrọ́ kíkan kúrò ní ilé yín, kí ẹ pa ẹni* tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà* láti ọjọ́ kìíní títí dé ìkeje ní Ísírẹ́lì.
3 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà pẹ̀lú rẹ̀;+ ọjọ́ méje ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, ó jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, torí pé ẹ kánjú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè kí o lè máa rántí ọjọ́ tí o kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
30Hẹsikáyà ránṣẹ́ sí gbogbo Ísírẹ́lì+ àti Júdà, ó tiẹ̀ tún kọ lẹ́tà sí Éfúrémù àti Mánásè,+ pé kí wọ́n wá sí ilé Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe Ìrékọjá sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
21 Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Jerúsálẹ́mù fi ọjọ́ méje ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ tìdùnnútìdùnnú,+ àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà sì ń yin Jèhófà lójoojúmọ́, wọ́n ń fi àwọn ohun èlò orin wọn kọrin sókè sí Jèhófà.+