-
2 Àwọn Ọba 24:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Lákòókò yẹn, àwọn ìránṣẹ́ Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dó ti ìlú náà.+
-
-
Jeremáyà 29:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jerúsálẹ́mù sí àwọn àgbààgbà tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó wà nígbèkùn àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, 2 lẹ́yìn tí Ọba Jekonáyà,+ ìyá ọba,*+ àwọn òṣìṣẹ́ ààfin, àwọn ìjòyè Júdà àti Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn oníṣẹ́ irin* ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+
-