7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+
9 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba+ pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù;+ ó tún sun ilé gbogbo àwọn ẹni ńlá.+10 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+