-
Ẹ́sírà 9:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Gbàrà tí a parí àwọn nǹkan yìí, àwọn olórí wá bá mi, wọ́n sì sọ pé: “Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká àti àwọn ohun ìríra wọn,+ ìyẹn àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì, àwọn ọmọ Ámónì, àwọn ọmọ Móábù, àwọn ará Íjíbítì+ àti àwọn Ámórì. + 2 Wọ́n ti fi lára àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, wọ́n sì tún fẹ́ wọn fún àwọn ọmọkùnrin wọn.+ Ní báyìí, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ* mímọ́+ ti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn àwọn ilẹ̀ tó yí wọn ká.+ Àwọn olórí àti àwọn alábòójútó sì ni òléwájú nínú ìwà àìṣòótọ́ yìí.”
-