ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 24:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí ìlú náà nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dó tì í.

  • 2 Àwọn Ọba 24:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba jáde kúrò.+ Gbogbo nǹkan èlò wúrà tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà+ ni ó gé sí wẹ́wẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́.

  • 2 Kíróníkà 36:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Nebukadinésárì kó lára àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà lọ sí Bábílónì, ó sì kó wọn sínú ààfin rẹ̀ ní Bábílónì.+

  • 2 Kíróníkà 36:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́, ńlá àti kékeré pẹ̀lú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba àti ti àwọn ìjòyè rẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló kó wá sí Bábílónì.+

  • Ẹ́sírà 6:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Bákan náà, kí a dá àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run pa dà, èyí tí Nebukadinésárì kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì,+ kí wọ́n lè pa dà sí àyè wọn nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí a sì kó wọn sínú ilé Ọlọ́run.’+

  • Dáníẹ́lì 1:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 1 Ní ọdún kẹta àkóso Jèhóákímù+ ọba Júdà, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì pàgọ́ tì í.+ 2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+

  • Dáníẹ́lì 5:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Nígbà tí wáìnì ń pa Bẹliṣásárì, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà tí Nebukadinésárì bàbá rẹ̀ kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá,+ kí ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, àwọn wáhàrì* rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ onípò kejì lè fi wọ́n mutí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́