11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+
35 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Wò ó, màá ṣẹ́ ọrun Élámù,+ tó jẹ́ agbára tó gbójú lé.*36 Màá mú ẹ̀fúùfù mẹ́rin láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run wá sórí Élámù, màá sì tú wọn ká sí gbogbo ẹ̀fúùfù yìí. Kò ní sí orílẹ̀-èdè kankan tí àwọn tí a fọ́n ká láti Élámù kò ní dé.’”