-
Nehemáyà 2:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Níkẹyìn, mo sọ fún wọn pé: “Ẹ wo ìṣòro ńlá tó wà níwájú wa, bí Jerúsálẹ́mù ṣe di àwókù, tí wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀. Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká tún ògiri Jerúsálẹ́mù mọ, ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìtìjú tó bá wa yìí.”
-
-
Dáníẹ́lì 9:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Mọ èyí, kó sì yé ọ pé látìgbà tí a bá ti pàṣẹ pé ká dá Jerúsálẹ́mù pa dà sí bó ṣe wà,+ ká sì tún un kọ́, títí di ìgbà Mèsáyà*+ Aṣáájú,+ ọ̀sẹ̀ méje máa wà àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta (62).+ Wọ́n máa mú kó pa dà sí bó ṣe wà, wọ́n sì máa tún un kọ́, ó máa ní ojúde ìlú, wọ́n sì máa gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká, àmọ́ á jẹ́ ní àkókò wàhálà.
-