-
Ẹ́kísódù 2:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún,* ọba Íjíbítì kú,+ àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kérora torí wọ́n wà lóko ẹrú, wọ́n sì ń ráhùn, igbe tí wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ torí pé wọ́n ń fi wọ́n ṣe ẹrú sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.+ 24 Nígbà tó yá, Ọlọ́run gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kérora,+ Ọlọ́run sì rántí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù dá.+ 25 Torí náà, Ọlọ́run yíjú sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; Ọlọ́run sì kíyè sí wọn.
-