14 Bákan náà, láti ọjọ́ tí ọba ti yàn mí láti di gómìnà wọn+ ní ilẹ̀ Júdà, láti ogún ọdún+ sí ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Ọba Atasásítà,+ ó jẹ́ ọdún méjìlá (12), èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ tó yẹ gómìnà.+
6 Ní gbogbo àkókò yìí, mi ò sí ní Jerúsálẹ́mù, nítorí mo lọ sọ́dọ̀ ọba ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Atasásítà+ ọba Bábílónì; lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo gba àyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.