13 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì mú Amasááyà ọba Júdà, ọmọ Jèhóáṣì ọmọ Ahasáyà, ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù láti Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Igun,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ìgbọ̀nwọ́.*
16 Ni àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó wọn wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà fún ara wọn, kálukú sórí òrùlé rẹ̀ àti sí àgbàlá wọn àti àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ bákan náà, wọ́n ṣe é sí gbàgede ìlú ní Ẹnubodè Omi+ àti gbàgede ìlú tó wà ní Ẹnubodè Éfúrémù.+