- 
	                        
            
            Ẹ́sítà 8:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        9 Torí náà, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba ní àkókò yẹn ní oṣù kẹta, ìyẹn oṣù Sífánì,* ní ọjọ́ kẹtàlélógún, wọ́n sì kọ gbogbo ohun tí Módékáì pa láṣẹ fún àwọn Júù àti fún àwọn baálẹ̀,+ fún àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè àwọn ìpínlẹ̀*+ tó wà ní Íńdíà títí dé Etiópíà, ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínláàádóje (127), wọ́n kọ ọ́ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè tirẹ̀, bákan náà, wọ́n kọ ọ́ sí àwọn Júù ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn àti ní èdè wọn. 
 
-