-
Ẹ́sítà 7:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nítorí wọ́n ti ta+ èmi àti àwọn èèyàn mi, láti pa wá, láti run wá àti láti pa wá rẹ́.+ Ká ní wọ́n kàn tà wá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin nìkan ni, mi ò bá dákẹ́. Àmọ́ àjálù náà kò ní bọ́ sí i rárá torí pé ó máa pa ọba lára.”
5 Ọba Ahasuérúsì wá béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítà Ayaba pé: “Ta ni? Ibo lẹni tó gbójúgbóyà ṣerú èyí wà?” 6 Ẹ́sítà sọ pé: “Elénìní àti ọ̀tá náà ni Hámánì olubi yìí.”
Jìnnìjìnnì bo Hámánì nítorí ọba àti ayaba.
-