6 Ní òru ọjọ́ yẹn, ọba ò rí oorun sùn. Torí náà, ó ní kí wọ́n mú ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn àkókò+ wá, wọ́n sì kà á fún ọba. 2 Nínú àkọsílẹ̀ náà, wọ́n rí ohun tí Módékáì sọ nípa Bígítánà àti Téréṣì, àwọn òṣìṣẹ́ méjì láàfin ọba tí wọ́n jẹ́ aṣọ́nà, àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Ọba Ahasuérúsì.+