-
Ẹ́sítà 3:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà ní ẹnubodè ọba máa ń tẹrí ba fún Hámánì, wọ́n sì ń wólẹ̀ fún un, nítorí ohun tí ọba pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣe fún un nìyẹn. Àmọ́ Módékáì kọ̀, kò tẹrí ba fún un, kò sì wólẹ̀. 3 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà ní ẹnubodè ọba béèrè lọ́wọ́ Módékáì pé: “Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ ọba mọ́?” 4 Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ kì í fetí sí wọn. Wọ́n wá sọ fún Hámánì láti mọ̀ bóyá ohun tí Módékáì ń ṣe bójú mu;+ torí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.+
5 Nígbà tí Hámánì rí i pé Módékáì kọ̀, kò tẹrí ba fún òun, tí kò sì wólẹ̀, Hámánì gbaná jẹ.+
-