ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 103:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ní ti ẹni kíkú, àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bíi ti koríko;+

      Ó rú jáde bí ìtànná orí pápá.+

      16 Àmọ́ nígbà tí atẹ́gùn fẹ́, kò sí mọ́,

      Àfi bíi pé kò sí níbẹ̀ rí.*

  • Àìsáyà 40:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń sọ pé: “Ké jáde!”

      Ẹlòmíì béèrè pé: “Igbe kí ni kí n ké?”

      “Koríko tútù ni gbogbo ẹran ara.*

      Gbogbo ìfẹ́ wọn tí kì í yẹ̀ dà bí ìtànná àwọn ewéko.+

  • Jémíìsì 1:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 àti ọlọ́rọ̀ torí a ti rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ torí ó máa kọjá lọ bí òdòdó inú pápá. 11 Bí oòrùn ṣe máa ń mú ooru tó ń jóni jáde tó bá yọ, tó sì máa mú kí ewéko rọ, tí òdòdó rẹ̀ á já bọ́, tí ẹwà rẹ̀ tó tàn sì máa ṣègbé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọlọ́rọ̀ máa pa rẹ́ bó ṣe ń lépa ọrọ̀.+

  • 1 Pétérù 1:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Torí “gbogbo ẹran ara* dà bíi koríko, gbogbo ògo rẹ̀ sì dà bí ìtànná àwọn ewéko; koríko máa ń gbẹ, òdòdó sì máa ń rẹ̀ dà nù,

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́