-
Nọ́ńbà 11:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Kí ló dé tí o fìyà jẹ ìránṣẹ́ rẹ? Kí ló dé tí o kò ṣojúure sí mi, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn èèyàn yìí lé mi lórí?+
-
-
Nọ́ńbà 11:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Tó bá jẹ́ ohun tí o fẹ́ ṣe fún mi nìyí, jọ̀ọ́ kúkú pa mí báyìí.+ Tí mo bá rí ojúure rẹ, má ṣe jẹ́ kí ojú mi tún rí ibi mọ́.”
-
-
1 Àwọn Ọba 19:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, torí náà, ó gbéra, ó sì sá nítorí ẹ̀mí* rẹ̀.+ Ó wá sí Bíá-ṣébà+ tó jẹ́ ti Júdà,+ ó sì fi ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀. 4 Ó rin ìrìn ọjọ́ kan lọ sínú aginjù, ó dúró, ó jókòó sábẹ́ igi wíwẹ́, ó sì béèrè pé kí òun* kú. Ó sọ pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Jèhófà, gba ẹ̀mí* mi,+ nítorí mi ò sàn ju àwọn baba ńlá mi.”
-
-
Jónà 4:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jèhófà, ṣebí ohun tí mo rò nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi ló wá ṣẹlẹ̀ yìí? Torí ẹ̀ ni mo ṣe kọ́kọ́ sá lọ sí Táṣíṣì.+ Mo ti mọ̀ pé Ọlọ́run tó máa ń gba tẹni rò* ni ọ́, o jẹ́ aláàánú, o kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi, inú rẹ kì í sì í dùn sí àjálù. 3 Jèhófà, jọ̀ọ́ gbẹ̀mí* mi, torí ó sàn kí n kú ju kí n wà láàyè.”+
-