-
Diutarónómì 6:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé òun máa fún ọ,+ àwọn ìlú tó tóbi tó sì dára, tí kì í ṣe ìwọ lo kọ́ ọ,+ 11 àwọn ilé tí gbogbo onírúurú ohun rere tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún kún inú wọn, àwọn kòtò omi tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, tí o jẹ, tí o sì yó,+ 12 rí i pé o ò gbàgbé Jèhófà,+ ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.
-
-
Jóòbù 31:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Tí mo bá gbẹ́kẹ̀ lé wúrà,
Àbí tí mo sọ fún wúrà tó dáa pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi!’+
-
-
Jóòbù 31:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà ni,
Torí màá ti fìyẹn sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ lókè.
-