23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+
27 Àwọn igi oko yóò so èso, ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ wọn yóò sì máa gbé láìséwu lórí ilẹ̀ náà. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà wọn,+ tí mo sì gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fi wọ́n ṣẹrú.