-
Nehemáyà 9:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Torí náà, àwọn ọmọ wọn wọlé, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà,+ o ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà níwájú wọn,+ o sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́, látorí àwọn ọba wọn dórí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè ṣe wọ́n bí wọ́n ṣe fẹ́. 25 Wọ́n gba àwọn ìlú olódi+ àti ilẹ̀ ọlọ́ràá,*+ wọ́n gba àwọn ilé tí oríṣiríṣi ohun rere kún inú rẹ̀, wọ́n gba àwọn kòtò omi tí wọ́n ti gbẹ́ síbẹ̀, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn oko ólífì+ àti àwọn igi eléso tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Torí náà, wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra, wọ́n gbádùn oore ńlá rẹ.
-