-
Jeremáyà 7:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ṣùgbọ́n, mo pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, màá sì di Ọlọ́run yín, ẹ ó sì di èèyàn mi.+ Kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.”’+ 24 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀,+ kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rìn nínú ètekéte* wọn, wọ́n ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ,+ ńṣe ni wọ́n ń pa dà sẹ́yìn, wọn ò lọ síwájú,
-
-
Jeremáyà 11:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nítorí mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín gidigidi ní ọjọ́ tí mò ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di òní, léraléra ni mo sì ń kìlọ̀* fún wọn pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi.”+ 8 Ṣùgbọ́n wọn ò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fetí sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, kálukú wọn ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ.+ Torí náà, mo mú gbogbo ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí wá sórí wọn, èyí tí mo pa láṣẹ fún wọn, tí wọn ò sì pa mọ́.’”
-
-
Míkà 6:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Torí ò ń tẹ̀ lé òfin Ómírì àti gbogbo ohun tí wọ́n ṣe ní ilé Áhábù,+
O sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn.
-