-
Àìsáyà 65:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Mo ti tẹ́ ọwọ́ mi sí àwọn alágídí láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+
Sí àwọn tó ń rìn ní ọ̀nà tí kò dáa,+
Tí wọ́n ń tẹ̀ lé èrò tiwọn;+
-
Ìsíkíẹ́lì 20:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “‘“Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, kò sì wù wọ́n láti fetí sí mi. Wọn ò ju ohun ìríra tó wà níwájú wọn nù, wọn ò sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin Íjíbítì sílẹ̀.+ Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì.
-
-
Sekaráyà 7:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀,+ agídí wọn mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi,+ wọ́n sì di etí wọn kí wọ́n má bàa gbọ́.+ 12 Wọ́n mú kí ọkàn wọn le bíi dáyámọ́ǹdì,*+ wọn ò sì tẹ̀ lé òfin* àti ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fi ẹ̀mí rẹ̀ sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́.+ Torí náà, inú bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gan-an.”+
-
-
-