1 Sámúẹ́lì 2:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Ó ń dáàbò bo ìṣísẹ̀ àwọn adúróṣinṣin rẹ̀,+Ṣùgbọ́n a ó pa àwọn ẹni burúkú lẹ́nu mọ́ nínú òkùnkùn,+Nítorí kì í ṣe nípa agbára ni èèyàn fi ń borí.+ Sáàmù 37:24 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 24 Bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ ṣubú, kò ní balẹ̀ pátápátá,+Nítorí pé Jèhófà dì í lọ́wọ́ mú.*+ Sáàmù 121:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ yọ̀.*+ Ẹni tó ń ṣọ́ ọ kò ní tòògbé láé. Ìdárò 3:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Nítorí ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé,+Nítorí àánú rẹ̀ kò ní dópin láé.+
9 Ó ń dáàbò bo ìṣísẹ̀ àwọn adúróṣinṣin rẹ̀,+Ṣùgbọ́n a ó pa àwọn ẹni burúkú lẹ́nu mọ́ nínú òkùnkùn,+Nítorí kì í ṣe nípa agbára ni èèyàn fi ń borí.+