ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 22:8-16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Ayé bẹ̀rẹ̀ sí í mì síwá-sẹ́yìn, ó sì ń mì jìgìjìgì;+

      Àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀run mì tìtì+

      Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí a ti mú un bínú.+

       9 Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,

      Iná tó ń jóni run jáde láti ẹnu rẹ̀,+

      Ẹyin iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

      10 Ó tẹ ọ̀run wálẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀,+

      Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+

      11 Ó gun kérúbù,+ ó sì ń fò bọ̀.

      A rí i lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.*+

      12 Ó wá fi òkùnkùn bò ó bí àgọ́,+

      Nínú ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀.

      13 Láti inú ìmọ́lẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀ ni ẹyin iná ti ń jó.

      14 Nígbà náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sán ààrá láti ọ̀run;+

      Ẹni Gíga Jù Lọ mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀.+

      15 Ó ta àwọn ọfà+ rẹ̀, ó sì tú wọn ká;

      Mànàmáná kọ, ó sì kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+

      16 Ìsàlẹ̀ òkun hàn síta;+

      Àwọn ìpìlẹ̀ ayé hàn síta nítorí ìbáwí Jèhófà,

      Nípa èémí tó tú jáde ní ihò imú rẹ̀.+

  • Sáàmù 77:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ìró ààrá rẹ+ dà bí ìró àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin;

      Mànàmáná tó ń kọ mú kí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé* mọ́lẹ̀;+

      Ayé mì tìtì, ó sì mì jìgìjìgì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́