17 Ó na ọwọ́ rẹ̀ láti òkè;
Ó mú mi, ó sì fà mí jáde látinú omi jíjìn.+
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+
Lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi, tí wọ́n sì lágbára jù mí lọ.
19 Wọ́n kò mí lójú ní ọjọ́ àjálù mi,+
Ṣùgbọ́n Jèhófà ni alátìlẹyìn mi.
20 Ó mú mi jáde wá sí ibi ààbò;+
Ó gbà mí sílẹ̀ nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.+