Sáàmù 46:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 46 Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa,+Ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.+ Àìsáyà 41:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+ Jeremáyà 20:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+ Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí. Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+ Hébérù 13:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+
13 Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+
11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+ Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí. Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+
6 Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+