4 Ó wá sọ fún un pé: “Sáré lọ síbẹ̀ yẹn, kí o sì sọ fún ọkùnrin yẹn pé, ‘“Wọn yóò gbé inú Jerúsálẹ́mù+ bí ìgbèríko gbalasa,* nítorí gbogbo èèyàn àti ẹran ọ̀sìn tó máa wà nínú rẹ̀.”+5 Jèhófà kéde pé, “Èmi yóò di ògiri iná fún un yí ká,+ màá sì mú kí ògo mi wà láàárín rẹ̀.”’”+