24 ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o ti ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ,+ àbí ọlọ́run wo ní ọ̀run tàbí ní ayé ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà bíi tìrẹ?+
11 Jèhófà, tìrẹ ni títóbi+ àti agbára ńlá+ àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá,*+ nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ.+ Jèhófà, tìrẹ ni ìjọba.+ Ìwọ ni Ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe olórí lórí ohun gbogbo.