ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 15:1-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?

      Ta ló lè máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?+

       2 Ẹni tó ń rìn láìlẹ́bi,*+

      Tó ń ṣe ohun tí ó tọ́+

      Tó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn rẹ̀.+

       3 Kò fi ahọ́n rẹ̀ bani jẹ́,+

      Kò ṣe ohun búburú kankan sí ọmọnìkejì rẹ̀,+

      Kò sì ba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórúkọ jẹ́.*+

       4 Kì í bá ẹnikẹ́ni tó jẹ́ oníwàkiwà kẹ́gbẹ́,+

      Àmọ́ ó máa ń bọlá fún àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà.

      Kì í yẹ àdéhùn,* kódà tó bá máa pa á lára.+

       5 Kì í yáni lówó èlé,+

      Kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti gbógun ti aláìṣẹ̀.+

      Ẹni tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, mìmì kan ò ní mì í láé.*+

  • Sáàmù 27:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà,

      Òun ni mo sì ń wá, pé:

      Kí n máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+

      Kí n máa rí adùn Jèhófà,

      Kí n sì máa fi ìmọrírì* wo tẹ́ńpìlì* rẹ̀.+

  • Sáàmù 65:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹ

      Kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.+

      Àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn,+

      Ìyẹn àwọn ohun inú tẹ́ńpìlì mímọ́* rẹ.+

  • Sáàmù 122:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 122 Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé:

      “Jẹ́ ká lọ sí ilé Jèhófà.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́