Nehemáyà 6:16 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 16 Nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá wa gbọ́, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wa ká sì rí i, ìtìjú ńlá* bá wọn,+ wọ́n sì rí i pé Ọlọ́run wa ló ràn wá lọ́wọ́ tí a fi lè parí iṣẹ́ náà. Àìsáyà 41:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+ Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+ Jeremáyà 20:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+ Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí. Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+
16 Nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá wa gbọ́, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wa ká sì rí i, ìtìjú ńlá* bá wọn,+ wọ́n sì rí i pé Ọlọ́run wa ló ràn wá lọ́wọ́ tí a fi lè parí iṣẹ́ náà.
11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+ Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+
11 Ṣùgbọ́n Jèhófà wà pẹ̀lú mi bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi á fi fẹsẹ̀ kọ, wọn ò sì ní borí.+ Ojú á tì wọ́n wẹ̀lẹ̀mù, torí pé wọn ò ní ṣàṣeyọrí. Wọ́n á tẹ́ títí láé, ẹ̀tẹ́ wọn ò sì ní ṣeé gbàgbé.+