-
Òwe 5:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Ó máa kú nítorí kò gba ìbáwí
Á sì ṣìnà nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù.
-
-
Málákì 3:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Èmi yóò sún mọ́ yín láti dá yín lẹ́jọ́, èmi yóò sì ta ko àwọn oníṣẹ́ oṣó láìjáfara,+ èmi yóò ta ko àwọn alágbèrè, àwọn tó ń búra èké,+ àwọn tó ń lu òṣìṣẹ́ àti opó àti ọmọ aláìníbaba* ní jìbìtì,+ títí kan àwọn tó kọ̀ láti ran àwọn àjèjì lọ́wọ́.*+ Wọn ò bẹ̀rù mi,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
-
-
1 Kọ́ríńtì 6:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà.* Àwọn oníṣekúṣe,*+ àwọn abọ̀rìṣà,+ àwọn alágbèrè,+ àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀,+ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀,*+ 10 àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò,+ àwọn ọ̀mùtípara,+ àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn* àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+
-