Sáàmù 19:9, 10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Ìbẹ̀rù Jèhófà+ mọ́, ó wà títí láé. Àwọn ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́, òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.+ 10 Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà,Ju ọ̀pọ̀ wúrà tó dáa,*+Wọ́n sì dùn ju oyin lọ,+ oyin inú afárá. Sáàmù 119:72 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 72 Òfin tí o kéde dára fún mi,+Ó dára ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.+ Sáàmù 119:127 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 127 Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹJu wúrà, kódà ju wúrà tó dára* lọ.+ Òwe 3:13-15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Aláyọ̀ ni ẹni tó wá ọgbọ́n rí+Àti ẹni tó ní òye;14 Kéèyàn ní in sàn ju kéèyàn ní fàdákà,Kéèyàn jèrè rẹ̀ sì sàn ju kéèyàn jèrè wúrà.+ 15 Ó ṣeyebíye ju iyùn* lọ;Kò sí ohun míì tí o fẹ́ tó ṣeé fi wé e.
9 Ìbẹ̀rù Jèhófà+ mọ́, ó wà títí láé. Àwọn ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́, òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.+ 10 Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà,Ju ọ̀pọ̀ wúrà tó dáa,*+Wọ́n sì dùn ju oyin lọ,+ oyin inú afárá.
13 Aláyọ̀ ni ẹni tó wá ọgbọ́n rí+Àti ẹni tó ní òye;14 Kéèyàn ní in sàn ju kéèyàn ní fàdákà,Kéèyàn jèrè rẹ̀ sì sàn ju kéèyàn jèrè wúrà.+ 15 Ó ṣeyebíye ju iyùn* lọ;Kò sí ohun míì tí o fẹ́ tó ṣeé fi wé e.