1Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà+ wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run,+ Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.*+2 Ẹni yìí wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀. 3 Ohun gbogbo wà nípasẹ̀ rẹ̀+ àti pé láìsí i, kò sí nǹkan kan tó wà.
14 Torí náà, Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara,+ ó gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, irú ògo tó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo+ ti bàbá kan; ó sì kún fún oore Ọlọ́run* àti òtítọ́.