26 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Jẹ́ ká+ dá èèyàn ní àwòrán wa,+ kí wọ́n jọ wá,+ kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, àwọn ẹran ọ̀sìn, lórí gbogbo ayé àti lórí gbogbo ẹran tó ń rákò tó sì ń rìn lórí ilẹ̀.”+
15 Òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí,+ àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá; +16 nítorí ipasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí,+ ì báà jẹ́ ìtẹ́ tàbí ipò olúwa tàbí ìjọba tàbí àṣẹ. Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀+ àti nítorí rẹ̀.