-
Òwe 1:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Ìgbà wo ni ẹ̀yin aláìmọ̀kan máa jáwọ́ nínú àìmọ̀kan yín?
Ìgbà wo ni ẹ̀yin afiniṣẹ̀sín máa gbádùn fífini ṣẹ̀sín dà?
Ìgbà wo sì ni ẹ̀yin òmùgọ̀ máa kórìíra ìmọ̀ dà?+
-
-
Róòmù 1:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre. 21 Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run, wọn ò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ìrònú wọn ò mọ́gbọ́n dání, ọkàn wọn tó ti kú tipiri sì ṣókùnkùn.+
-